General note:
|
Orúkọ Yorùbá jẹ́ ohun pàtàkì tí àwọn Yorùbá ń lò jákè-jádò gbogbo ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè Yorùbá bí Ìbíní,Tógò àti Nàìjíríà. Nípaṣe ìṣe àwọn baba ńlá baba àwọ́n Yorùbá, eọ́n ń fún ọmọ wọn lórúkọ níbi ayẹyẹ tí ó máa ń wáyé ní ọjọ́ kẹẹ̀jọ lẹ́yìn ìbímọ.Àwọn orúkọ àwọn ọmọ jẹ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ nípa ifá dídá tí ọ̀pọ̀ Babaláwo bá dá, ṣùgbọ́n ní ayé òde-òní, orúkọ ọmọ tún lè wá láti ọ̀dọ àwọn tí ó bá ní ipò tóga nínú ẹbí pẹ̀lú bàbá,ìyá,òbí àwọn òbí méjéèjì tàbí ẹni tí ó súnmọ́ wọn gbágbá.Ìyá àti bàbá,àti alásùn-ún-mọ́ wọn lè fún ọmọ tàbí àwọn ọmọ ní orúkọ tóbá wù wọ́n.Orúkọ ọmọ sáábà máa ń wá láti ọ̀dọ àwọn òbí méjéèjì ìyá àti bàbá ọmọ àti àwọn obí tó bí òbí méjéèjì yí wọ́n bí ọmọ tí wọ́n fẹ́ sọ lórúkọ.orúkọ ìbílẹ̀ tí a dífá fún láti ọ̀dọ Babaláwo ń ṣe àfihàn òrìṣà tó ń ṣe atọ́nà ọmọ náà wá sáyé, yálà ọmọ náà jẹ́ àtúnbí oònilẹ̀ àtipé kádàrá ọmọ àti nípa ti ẹ̀mí tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí,tí ó máa ran ọmọ náà lọ́wọ́ láti lè jẹ́ kí ó tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́.Ayẹyẹ ìkọ̀kọ̀ àkọ́kọ́ kan tún wà fún ìyá àti bàbá ọmọ nìkan níbi tí orúkọ àti èèwọ̀ yóò ti máa jẹ́ fífún ọmọ àti òbí rẹ̀,àti àbá lórí ohun tí ọmọ náà máa nílò láti fi ṣe àṣeyọrí.Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìnáwó àwùjọ tí àsè àti àríyá ti wáyé tí ẹbí àti ojúlùmọ̀ sì ti jẹ́ ìpè àwọn obí ọmọ láti wá báwọn ṣàjọyọ̀ ìbí ọmọ náà.
|